k yìnbó (Live)-文本歌词

k yìnbó (Live)-文本歌词

K1 De Ultimate
发行日期:

Shaky bọ̀bọ́, Shakiru o ṣé

Aya mi ńkọ́? Àwọn ọmọ mi ńkọ́?

Shaky, awo tèmi Àyìndé ‘mọgbọ́láhàn

Toheeb ẹbakajuyi l’áyépé

Awo Jídé Nagatha, oṣé modúpẹ́ Shakky Shakiru

Shakky bọ̀bọ́ mi

Awo tèmi Àyìndé ‘mọ́gbọ́láhàn arábámbí

Àkànní Rasaki Ọláńrewájú, Lord mayor jókòó jókòó

Mo kàn ń f’orin kí ẹ ni Àkànní adé

B’éèyàn bá rí ọlọ́rọ̀ ẹni ọmọ sọ̀rọ̀ sọ̀rọ̀ làà dà Olúayé Fújì arábámbí

Bó o náwó, bó ò náwó, o ti náwó ọdún mẹ́ta sílẹ̀ arábámbí

Ẹrù tó ń bẹ nílẹ̀ ó tó pín

Walahi, mo f’Ọlọ́run búra Wasiu Àyìndé

Ó ti náwó ọdún mẹ́ta sílẹ̀ bí ò bá náwó

Bí èèyàn bá rí ọlọ́rọ̀ ẹni, Walahi Ishola Rauf ọmọ Ìyálájé

Ìwọ náà, o ti náwó I ọdún mẹ́jọ sílẹ̀ Ishola adé

AR share Dáre ọkọ Suraja

Ẹ̀bà Kadiri, gbogbo àwọn tó ń t’ọwọ́ bọ àpò

Tó ń ná mi lówó

Náwó náwó kì ń ṣe ọ̀dẹ̀ Wasiu Àyìndé

Walahi, mo f’Ọlọ́run búra Àyìndé o

Àṣírí yín, Àkànní á tú bọ̀ máa bò si o

Gbogbo ẹ̀yin ọmọ náwó náwó, ẹ ò ní ná ìkan tan kí ẹ tó rí ìmíì si lọ́lá Ọlọ́run Ọba ẹ̀yin ọmọ náwó náwó

O ṣé Shekin awo tèmi Ọmọ́gbọ́láhàn arábámbí

Ẹ̀bà, ọmọ Kadiri ní Ìjẹ̀bú ayépé

Ọkọ Muniratu mi

Ihun bá wù ẹ́ ko fowó tì ẹ rà tèmi dá mi lójú

Náwó náwó ń fowó ra’yì náà ni

Ọmọ Kura, a kìí láhun níyì, ló dífá fún gbogbo náwó náwó

Olówó ń fowó ra iyì náà ni

Ẹ̀bẹ̀ tí mò ń bẹ Ọlọ́hun Ọba Àyìndé adé

Ọba má pa kádàrá wa dà sábùru

Ọláńrewájú, Àkànní ń fowó rayì náà ni

Ọba Ẹ̀bà Kádírì, awo ti sẹ́gun sẹ́gun mo gbà fún ẹ tó

Ọmọ Aṣọ́kọyà mi o aláṣẹ SOB auto

Ọkọ Àánúolúwa bàbá Àńjọlá, awo Joseph dada

Ẹ̀bà ọmọ Kádírì, Toheeb ilé ìyá ẹ Òbíǹjá ará ìlódò ṣá ni ẹ́

Ọmọ ọmọ Saluwala

Ọmọ Tápà Olúbísí, láyépé tún ni ilé ẹ níjẹ̀bú o

Ìyẹn ní ilé Bàbá ẹ

Àna t’Amraf torí Rafiatu yìí Rafia

Sweety Rafiatu mi

Àkànní Rasaki Ọláńrewájú

Bí o bà náwó, bí ò bá náwó, ẹ ti náwó ọdún mẹ́jọ sílẹ̀ arábámbí

Àkànní Rasaki Ọláńrewájú Aláṣẹ R & A Suites

Ìyẹ ni wọ́n ó máa wò lẹ́yìn ẹyẹ

Ńṣe ni wọ́n ń bá Ọya jà Ṣàngó ló ni ṣẹ́ẹ́rẹ́

Lanrewaju o káre Àkànní o.

Ọláńrewájú ọmọ Mashika

Ẹ̀gbá nílé ‘mọlíṣàbi Àkànní Ọláńrewájú

Ọkọ Òyìnbó mi Simbi mi o káre aya bàbá

Ọlá bàbá Isha yìí o ṣé

Simbi, ẹ̀yìn òyìnbó lèmi mà wà o

Simbi mi (Simbi mi)

Òun l’òyìnbó Lamex (Simbi mi)

Simbi òun l’òyìnbó Lamex (Simbi mi)

Ṣé ẹ̀yin náà, ṣé ẹ̀ ń r’óyìnbó

B’ó wu Nepa kó paná Àyìndé Wasiu (Ṣé ẹ̀ ń r’óyìnbó)

Àkànní, bó bá wu Nepa kó paná, ẹ wo òyìnbó Simbi

(Ṣé ẹ̀ ń r’óyìnbó)

Simbi òun ni’ná Ọlọ́hun! (ṣé ẹ̀ ń r’óyìnbó)

Simbi òun ni’ná Ọlọ́hun! (ṣé ẹ̀ ń r’óyìnbó)

Iná Ọlọ́hun ṣá ni Simbi (ṣé ẹ̀ ń r’óyìnbó)

Iná Ọlọ́hun ṣá ni Simbi (ṣé ẹ̀ ń r’óyìnbó)

Ẹ sọ bó wu Nepa kó paná (bó wu Nepa kó paná)

Bó wu Nepa kó paná (bó wu Nepa kó paná)

Àkànní ò ní sùn l’óòkùn bó wu ọlá Ọlọ́hun

(Bó wu Nepa kó paná)

Torí òyìnbó ni Simbi (Simbi mi)

Nítorí òyìnbó ni Simbi (Simbi mi)

Òun ni’ná Ọlọ́hun (Simbi mi)

Iná Ọlọ́hun! (ṣé ẹ̀ ń r’óyìnbó)

Simbi aya Ọláńrewájú Rasaki (Simbi mi)

Ewo òyìnbó Lamex (Simbi mi)

Raufu, ẹ wo òyìnbó Lamex (Simbi mi)

Bàbá Ayi (Bàbá Aisha)

Bàbá Ayi (Bàbá Aisha)

Aya t’Akanni mi Lord Mayor (Simbi mi)

Aya t’Akanni mi Lord Mayor (Simbi mi)

Bá n k’Óyìnbó (bá n k’Óyìnbó)

Bá n k’Óyìnbó (bá n k’Óyìnbó)

Bá n k’Óyìnbó (bá n k’Óyìnbó)