LAMEX (Live)-文本歌词

LAMEX (Live)-文本歌词

K1 De Ultimate
发行日期:

Ẹ f’orin ayọ̀ gbe wọ’lé

Àkànní Rasaki mi ọkọ òyìnbó mi Simbi mi

(Ẹ f’orin ayọ̀ gbe wọ’lé)

Ọláńrewájú Rasaki yìí o

Àkànní ẹ kí ọkọ Simbi bàbá Ayi

Àkànní owó ni wọ́n fi ń ṣe ilé ayé

Ara òní kan ẹ́ gógó alákànní o

Ìyẹ́ ni wọ́n ó máa wò lẹ́yìn ẹyẹ

Bí wọ́n bá ń f’owó ṣayé

Wọ́n á rí money lò sẹ́ o

Àkànní, owó òní tán lọ́wọ́ ẹ ò Ọláńrewájú

Àkànní mi Rasaki, eh ba

Iṣẹ́ ẹ ò ní di iṣẹ́ oníṣẹ́

Àkànní ọ̀nà omi ń bá wọ inú àgbọn o

T’áyé bá sá pamọ́, wọn ò le è ri

Àkànní mi Rasaki, ọmọ Mashika

Ọláńrewájú Aláṣẹ R & A Suite

Ìwọ ṣá ni Lord Mayor nínú ẹgbẹ́

Royal Pioneer mi Àkànní adé

Awo Túndé ọmọ Bọ̀rọ̀kìní

Awo Barrister lawyer ọ̀náfuwá, awo Olúayé onífujì mi

Àkànní adé, ọmọ ènìyàn ló ń jẹ́ aníbiíre sẹ́ o

Ọláńrewájú Ọlọ́run kò re ibì kan

Ìyẹ́ ni wọ́n ó máa wò

Ọ̀tá tí o rí mi ò fẹ́ ó kú

Àkànní! Ọ̀tá ẹ mi ò fẹ́ ó rùn

Ṣùgbọ́n ṣojú ọ̀tá a máa gbé ilé ayé ṣe dáadáa Àkànní adé

Ọlá bàbá Aishat mi, Ọláńrewájú Rasaki Àkànní adé

Àkànní wà á jèrè o

Ọmọ l’Àkànní Ọláńrewájú

Ọláńrewájú mi Rasaki

Àkànní Muhammed Ọláńrewájú (Ọláńrewájú Rasaki mi)

Àní ojú kìí ti oṣù kò mà ní t’owó (Ọláńrewájú Rasaki mi)

Ìwọ l’Òṣupá, (ìwọ nìràwọ̀)

Ìwọ l’Òṣupá, (ìwọ nìràwọ̀)

(Ìwọ lò ń gbé fàájì wá’yé)

Ta ló ń ṣe agídí Agídí

(Agídí ò rán ọ)

Àkànní ta ló ń ṣ’agídí ṣ’agídí

(Agídí ò rán o)

Ọláńrewájú, ẹ rọra dìtẹ̀, dìtẹ̀, dìtẹ̀

(K’ọ́tẹ̀ má tẹ̀yín o)

Àkànní, kí wọ́n rọra dìtẹ̀, dìtẹ̀, dìtẹ̀

(K’ọ́tẹ̀ má tẹ̀wọ́n o)

Àkànní adé mi Ọláńrewájú

Àkànní adé mi ọkọ t’Òyìnbó mi Simbi mi o

(Àkànní adé mi)

(Àkànní adé mi ọkọ t’Òyìnbó mi Simbi mi o)

Ọláńrewájú, àtòkè, àtilẹ̀, àtihùn

Òkìkí kìí pa oṣù ariwo ọjọ́ kìí pa ọjọ́

Lanrewájú Àkànní adé mi

Awo Mayor Akínpẹ̀lú, ọmọ Shadini ní’jẹ̀bú o

Àkànní adé mi, láńréwájú mi lamex mi o

(Àkànní adé mi)

(Àkànní adé mi ọkọ t’Òyìnbó mi Simbi mi o)

Èní alákànní, Àkànní

Ọ̀la Alákànní

Èní alákànní, Àkànní

(Ọ̀la alákànní)

Láńréwájú Àkànní mi Lamex (Rasaki mi Àkànní adé)

Òun lọkọ òyìnbó mi Simbi (Láńréwájú Rasaki mi)

(Ọ̀rọ̀ bí ẹkún kò ń bá Olúwa)

(Ọ̀rọ̀ bí òṣé, kò ń b’ólúwa Èdùmàrè)

(Ọba Ọlọ́hun kó má fi sọ́rọ̀ ẹ)

(Láńréwájú Rasaki ẹ k’Àkànní o)

Ẹ̀rín ni wọ́n ń dá pa ara wọn, ìyà ni wọ́n ń sá jẹ ara wọn

Ẹgbẹ̀rún otòṣí tó yan ọlọ́rọ̀ méjì

(Ebi ni wọ́n ń dá pa ara wọn)

Ó yá Rasaki mi Àkànní (Rasaki mi Àkànní)