Ye! Ye! Ah ah
Ọba ló ní n kí ẹ (Mọ́délé Baby)
Awo Bukky mí (awo Bukky mi)
Awo Àbíkẹ́ Adé mi o (Fausatu mi)
Àbíkẹ́ mi l’America (Á bá ire wá sílé)
Fausa l’America (á bá ire wá sílé)
Yẹ! Oṣé o Mọ́délé Baby (o ṣé Mọ́délé baby)
Àwọn mẹ́ta ni wọ́n jọ ń rìn
Òun pẹ̀lú Bukky (awo Mọ́délé baby)
Àwọn mẹ́ta ni wọ́n jọ ń rìn àti Àbíkẹ́ adé mi (Fausatu mi)
Ìyẹn aya Adele shantau (Fausatu mi)
Aya Adele mi Samson (Fausatu mi)
Ó ń bẹ l’America (á bá ire wá sílé)
Àbíkẹ́ tó ń bẹ l’America (wọ́n á bá ire wá sí ilé)
Mọ́délé jẹ́ n ríjó ọwọ́ ẹ o (Mọ́délé Baby)
Ye! Ye!
Jẹ́ n ríjó ọwọ́ ẹ o (Mọ́délé Baby)
Ọ̀rẹ́ Bukky (ọ̀rẹ́ Bukky)
Bukky baby, ìyẹn aya Sakariyawu (Bukky mi)
Aya Saka igbira, aya sakariyawu (Bukky mi)
Aya Fọlábí, clearing and forwarding agency (Bukky mi)
Saka, awo tèmi Àyìndé Wasiu (arábámbí)
Ojúṣàágbọlá ọ̀gọjì (Adégoróyè Ọba)
Ṣé ẹ̀ ń r’Áyìndé? (ṣé ẹ̀ ń r’Áyìndé? )
Ọkọ Àdùfẹ́ Fathia (Ọpẹ́yẹmí)
Ọkọ Àdùfẹ́ Fathia (Ọpẹ́yẹmí)
Àyìndé Bàbá Melissa (àkànkẹ́ adé)
Ọmọ mi Àkànkẹ́ Melissa (Àkànkẹ́ adé)
Ṣadé Solat ọmọ olọ́jọ́ ìbí Solat
Ẹ̀mí ẹ á ṣe púpọ̀ ọdún láyé, happy Birthday to you
Tí n bá kúrò lórí Abbey màá bọ́ sórí gbogbo ẹgbẹ́, Àyìndé mi Gbọ́láhàn pátápátá
Alhaja Bukky a ri yín ní ìdúnta, a ri yín léṣìín
A rí I yín lọ́dún yìí, gbogbo ìgbà tí ayé bá ń jẹ́ ayé
A ò ní fi ẹ́ ṣe àwátì arábámbí, ìwọ àti sakariyawu iná tí ẹ dá
Á se iṣu fún un yín, á jiná á se ọbẹ̀ fun yín á jiná
Ẹ̀ ẹ́ jẹ ẹ́…
Gbogbo wa ti jọ ń bá ara wa bọ̀ tipẹ́ tipẹ́
Ọ̀rẹ́ kìí ya Ọ̀rẹ́ awo ò gbọdọ̀ ya ara wọn
Ó da ká lẹ́ni lẹ́yìn, ẹní bá lẹ́ni lẹ́yìn ohun gbogbo ló ní
àdúrà wa ti gbà gbogbo wa
Mo kí ẹ pélé Modina, ó ṣé
Ọmọ mi tí ń jẹ́ Modina, ọmọ ni ẹ́ pélé pélé
Àní a ti jọ ń jayé bọ̀ tipẹ́tipẹ́
Pelesco, ọmọ ni ẹ́ Modinatu
Èèyàn tó bá fojú di ẹ́, ó fojú d’Ọlọ́hun Ọba ni Modinatu Pélé
Ìyà ni ó jẹ Olúwa ẹ
Ihun wu ẹlẹ́nu ló lè wí o, jẹ́ wọn ó wí
Ikú òní pa ọmọ fún ẹ o sweetie Modinatu Pélé
Awo Mọ́délé baby mi sweetie o ṣé
Pélé o, pélé o káre Modina
Awo honorable Adébísí Bassy
Modinatu o ò ní ṣubú pélé pélé
Bí mo ṣe ń ki pélé Modina arábámbí
Ṣadé mi sala máa gbọ́ bí mo ṣe ń wí
Ọmọ ọ lọ́jọ́ ibí ẹ̀mí ẹ á ṣe púpọ̀ ẹ o
Ganiyu dà?
Àbúrò àmọ̀kẹ́ Fausatu Abíọ́lá
Ajíkawó mi àmọ̀kẹ́ adé ńkọ́?
Fausa nílùú America á bá ire wálé
Ìlù Providence ṣá lo wà Fausa Fausa
Awo Àmọ̀rí, Àyìnkẹ́ adé mi Bíọ́lá
Biọ́lá baby (Biọ́lá baby)
Awo Mọ́délé baby mi (Biọ́lá baby)
Biọ́lá baby (Biọ́lá baby)