Agogo kó ró (agogo kó máa ró)
Agogo kó ró (agogo kó máa ró)
Agogo kó ró (agogo kó máa ró)
Ah! Bí gbogbo wa bá ń jó (omele kó máa ró)
Bí gbogbo wa bá ń jó (omele kó máa ró)
Bí Ah! Tiwa làlùjó Fújì o
Bí gbogbo wa bá ń jó (omele kó máa ró)
Bí gbogbo wa bá ń jó o (omele kó máa ró)
Tìẹ́pọ̀, èèyàn t’Allen Shico ọmọ àdúgbò mi
Ó pọ̀ fún ẹ púpọ̀ torí pé tì ẹ́ pọ̀
Abímbọ́lá mo rí ẹ lọ́dún yìí
Màá rí ẹ lẹ̀ míì tọmọ tọmọ lọ́lá Ọlọ́hun ọlá mother Jayden
Olúwafẹ́mi ọmọ Adébáyọ̀ ọmọ tí wọ́n ń sọ lọ́wọ́
Ijó ń bẹ ìyẹn ẹ̀wẹ̀dẹ̀ (ijó ń bẹ ìyẹn ẹ̀wẹ̀dẹ̀)
Àrẹ̀mú mi Báyọ̀ ọmọ Ọláṣojú dà?
Ahn Ahn! Mo sọ bẹ́ẹ̀
Àwọn Débáyọ̀ méjèèjì
Tí ẹ bá máa rí wọn àwọn méjèèjì wọ́n ń ṣe bíi 5&6
Ibi tí ìkan bá wà ìkejì máa dúró sí
Ah ah mo gbà pé’jó ń bẹ ìyẹn ẹ̀wẹ̀dẹ̀ (ijó ń bẹ ìyẹn ẹ̀wẹ̀dẹ̀)
Àṣàkẹ́, mo gbà pé’jó ń bẹ ìyẹn ẹ̀wẹ̀dẹ̀ (ijó ń bẹ ìyẹn ẹ̀wẹ̀dẹ̀)
Mojísọ́lá, mo gbà pé’jó ń bẹ ìyẹn ẹ̀wẹ̀dẹ̀ (ijó ń bẹ ìyẹn ẹ̀wẹ̀dẹ̀)
Fẹ́mi bo bá ṣe sí mi Ọmọtógbọ́láhàn (ma f’ọgbọ́n ta ẹ́ yọ)
Bo tún ṣe sí mi bó d’ẹlẹ́ẹ̀kejì (ma f’ọgbọ́n ta ẹ́ yọ)
Bo ṣe sí mi bó d’ẹlẹ́ẹ̀kẹta (ma f’ọgbọ́n ta ẹ́ yọ)
Àmọ̀kẹ́, mo ṣe pé ṣe pé o (o ṣe pé ṣe pé)
O ṣe pé ṣe pé o (o ṣe pé ṣe pé)
Pé o, pé o, pé o, pé o
Fúnkẹ́, mo ṣe pé ṣe pé (Mo ṣe pé ṣe pé)
Détulà mo ṣe pé ṣe pé (mo ṣe pé ṣe pé)
Gbogbo yín ẹ kú ọdún àti ẹ̀yin tí mo rí àti ẹni tí mi ò tíì rí
Mo ṣe pé ṣe pé (mo ṣe pé ṣe pé)
K1 Fans Club, President àti ti Nigeria pẹ̀lú worldwide ọmọ Bíléwú
Mo ṣe pé ṣe pé o (mo ṣe pé ṣe pé)
Ṣe pé tí mo wí olúọmọ of Lagos (la fi ọgbọ́n ta wọ́n yọ)
Ṣe pé tí mo wí olúọmọ of Lagos (la fi ọgbọ́n ta wọ́n yọ)
Ṣe pé tí mo wí olúọmọ of Lagos (la fi ọgbọ́n ta wọ́n yọ)
Ṣe pé tí mo wí olúọmọ of Lagos (la fi ọgbọ́n ta wọ́n yọ)
Bí wọ́n bínú n ó máa r’àdúgbò mi (n ó máa r’àdúgbò mi o)
Ò ń bẹ́
Mo ní mo bínú mo fẹ́ máa r’àdúgbò mi
O ṣì tún ń lùlù (mo fẹ́ máa r’àdúgbò mi o)
Ma bínú bínú n ó máa r’àdúgbò mi
Bẹ bínú bínú (n ó máa r’àdúgbò mi o)
Okay now, tó bá fẹ́ ṣe
Gbogbo àṣà tí mo bá ń dá (Àyìndé mi Gbọ́láhàn ó kẹ̀dẹ̀ ní reason)
Gbogbo àṣà tí mo bá ń dá (Àyìndé mi Gbọ́láhàn ó kẹ̀dẹ̀ ní reason)
Ó kẹ̀dẹ̀ ní reason o (ó kẹ̀dẹ̀ ní reason)
Àní ó kẹ̀dẹ̀ ní reason (ó kẹ̀dẹ̀ ní reason)
Àṣà tí mo bá ń dá (Àyìndé mi Gbọ́láhàn ó kẹ̀dẹ̀ ní reason)
Àṣà tí mo bá ń dá (Àyìndé mi Gbọ́láhàn ó kẹ̀dẹ̀ ní reason)
Golobal ló ń bọ́ o (Golobal ló ń bọ́ o)
Golobal ló ń bọ́ o (Golobal ló ń bọ́ o)
Ah! Golobal ló ń bọ́ o (Golobal ló ń bọ́ o)
Ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ yìí (Ẹní bà ló mọ̀ o)
Ah! Ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ yìí (ẹní bà ló mọ̀ o)
Akin ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ yìí (ẹní bà ló mọ̀ o)
Eluku ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ yìí (ẹní bà ló mọ̀ o)
Ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ yìí (ẹní bà ló mọ̀ o)
Ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ yìí (ẹní bà ló mọ̀ o)
Ah! Àlùjó leré Fújì (ṣé ẹ̀ ń r’Áyìndé)
Àlùjó leré Fújì (ṣé ẹ̀ ń r’Áyìndé)
Àlùjó leré Fújì (ṣé ẹ̀ ń r’Áyìndé)
Àlùjó leré Fújì (ṣé ẹ̀ ń r’Áyìndé)
Okay now, ẹ tú’jó sí wọn lára (bàbá olóyè ló ń bọ́)
Ẹ tú’jó sí wọn lára (bàbá olóyè ló ń kí)
Afiso àlùjó leré Fújì (ṣé ẹ̀ ń r’Áyìndé)
Àlùjó leré Fújì (ṣé ẹ̀ ń r’Áyìndé)
Afiso ìsẹ̀nyí ni inúù mí dùn (ṣé ẹ̀ ń r’Áyìndé)
Ìsẹ̀yí ní inúù mí dùn (seyẹ̀ ń r’Áyìndé)
Ah! Ló bá tikẹ̀kùn mọ́ wọn (ó fi kọ́kọ́rọ́ pamọ́)
Ó tikẹ̀kùn mọ́ wọn ( ó fi kọ́kọ́rọ́ pamọ́)
Ó tikẹ̀kùn mọ́ wọn ( ó fi kọ́kọ́rọ́ pamọ́)
Ó tikẹ̀kùn mọ́ wọn ( ó fi kọ́kọ́rọ́ pamọ́)
Ṣé ẹ̀ ń r’Áyìndé? (ṣé ẹ̀ ń r’Áyìndé)
Fẹ́mi ṣé ò ń rí bọ̀bọ́? (ṣé ò ń rí bọ̀bọ́)
Ah! Jagun jagun ṣé ẹ̀ ń r’Áyìndé? (ṣé ẹ̀ ń r’Áyìndé)
Jagun jagun ṣé ẹ̀ ń r’Áyìndé? (ṣé ẹ̀ ń r’Áyìndé)
Àlùjó leré Fújì (ṣé ẹ̀ ń r’Áyìndé)
Àlùjó leré Fújì (ṣé ẹ̀ ń r’Áyìndé)
Àlùjó leré Fújì (ṣé ẹ̀ ń r’Áyìndé)
Ah Fújì mi (Fújì mi)
Fújì mi (Fújì mi)
Fújì mi (Fújì mi)
W’àgàràú area (Fújì mi)
W’àgàràú area (Fújì mi)
Shibo!
Ọlọ́hun mi o (Bàbá o ṣé)
Tòótọ́ àríyá la bá wá bí
A à lè ṣe ká má gbàá l’ádùáà
Ojúu wa tó rọ́dún ẹ̀míi wa á ṣe púpọ̀ ẹ̀ ọdún láyé
Láti látarias fún iye ọdún tó jẹ́
A tún ti b’ára wa níbí báyìí
Ẹjọ́ ẹlẹ́jọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀ lọ́dún tuntun Ọmọ́gbọ́láhàn mi kò ní di tiwa
Àwọn apanijayé ò ní pàwajayé
Kìí ṣe ẹni tí wọ́n pa sọ́run nìkan ni wọ́n pa
Àìmọye èèyàn ló ń rìn ó dàbí òkú nílé ayé
Mo wá ń bẹ̀ ẹ́ Ọlọ́run Ọba tí a tún máa fi ríra wa
Ẹ jẹ́ ká máa ṣ’àdúrà ohun ta bá ń fẹ́
Ọlọ́hun mi o (Bàbá o ṣé)
Torí mo rọ̀wọ́ ìkẹ́ Ọlọ́hun (mo ri nínú iṣẹ́ mi)
Ìwọ náà wà á r’ọ́wọ́ àánú Ọlọ́hun Ọba (wà ri lórí iṣẹ́ ẹ)
Èmi r’ọ́wọ́ àánú Ọlọ́hun mo rí nínú iṣẹ́ mi
Wasiu Àyìndé mo ní mo rọ́wọ́ ìkẹ́ Ọlọ́hun mo ri nínú ayé mi
Jíjẹ mímu nírọ̀rùn la ṣe ń dúpẹ́ fún Ọlọ́hun
Àní ká lọ ká bọ̀ ní pesẹ̀ la ṣe ń dúpẹ́ fún Ọlọ́hun
Ẹní m’oore Ọlọ́run o ya tú Kẹ̀kẹ́ ijó sílẹ̀ ó yá
(M’oore Ọlọ́hun, tó bá m’oore Ọlọ́hun)
(Kó tú Kẹ̀kẹ́ ijó sílẹ̀ ó yá)
Ìwọ to bá m’oore Ọlọ́hun o
To m’oore Ọlọ́hun ya tú Kẹ̀kẹ́ ijó s8lẹ̀ ó yá o
(M’oore Ọlọ́hun tó bá m’oore Ọlọ́hun)
(Kó tú Kẹ̀kẹ́ ijó sílẹ̀ ó yá)
Ògbùró fi’ṣẹ́ tó ń ṣe sílẹ̀ wá jó ó ń kí
Mojísọ́lá ọmọ ẹ̀lẹ̀ yìí fi’ṣẹ tó ń ṣe sílẹ̀ (wá jó ó ń kí)
Ọkọ ìyàwó fi’ṣẹ́ tó ń ṣe sílẹ̀ wá jó (ó ń kí)
Ijọ́ ó bá fẹ́ sin’mọ níyàwó (báwo lo ti a jó o)
Ijọ́ ó bá fẹ́ sin’mọ níyàwó (báwo lo ti a jó o)
Àní Ijọ́ o bá fẹ́ ṣègbéyàwó (báwo lo ti a jó o)
Kíámọ́sá ya dìde ńlẹ̀ ko mújó ọ̀rọ̀ rèé ijó oge (bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ ko mújó oge)
Kíámọ́sá ya dìde ńlẹ̀ ko mújó ọ̀rọ̀ rèé ijó Ògé o (bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ ko mújó oge)
Ó dàbọ̀ ọjà o
Ó dàbọ̀ ọjà o
Ka dẹ̀ ì mújó yẹn tó kù ó di b’álé bá lẹ́ (ó dàbọ̀ ọjà o)
Ka dẹ̀ ì mújó yẹn tó kù ó di b’álé bá lẹ́ (ó dàbọ̀ ọjà o)
Ká í mújó yẹn tó kù ó di b’álé bá lẹ́ (ó dàbọ̀ ọjà o)
Ká í mújó yẹn tó kù ó di b’álé bá lẹ́ o (ó dàbọ̀ ọjà o)
Simbi, bí n bá ṣe báyìí o (àrà me dá)
Bí n ṣe báyìí (àrà me dá)
Bí n tún ṣe bẹ́ẹ̀ sẹ́ (àrà me dá)
Bí n ṣe bẹ́ẹ̀ sẹ́ (àrà me dá)
Bi ń ṣe báyìí ṣẹ́ o (àrà me dá)
Wọn ti ṣe sọ̀rọ̀ mi sí
Òní pélé alábàjà o wọ́n ti ṣe sọ̀rọ̀ mi sí o
(Ẹ ti ṣe sọ̀rọ̀ mi sí)
(Ẹ ti ṣe sọ̀rọ̀ mi sí)
(Òní pélé alábàjà o, ẹ ti ṣe sọ̀rọ̀ mi sí o)
Ó dàbọ̀ ọjà o
Ka dẹ̀ ì mújó yẹn tó kù ó di b’álé bá lẹ́ (ó dàbọ̀ ọjà o)
Ka dẹ̀ ì mújó yẹn tó kù ó di b’álé bá lẹ́ (ó dàbọ̀ ọjà o)
Ma fẹjọ́ sùn fún ìjòyè fẹjọ́ sùn f’Ọ́ba (ó dàbọ̀ ọjà o)
Ma r’ẹjọ́ mi fún Ṣàngó, r’ẹjọ́ mi fún ọpa (ó dàbọ̀ ọjà o)
Ah ah ah!