dúrà dún (Live)-文本歌词

dúrà dún (Live)-文本歌词

K1 De Ultimate
发行日期:

Ayọ̀ ọmọ Bákàrè, ẹsẹ̀ ẹ ò ní sì ńlé

Nínú ọdún wàá rówó pè ránsẹ́

O péjú síbí lọ́dún tó kọjá

A ríra wa lọ́dún yìí, o tún wa gbàdúrà ọdún míì sílẹ̀

Lágbára Ọlọ́hun Ọba, ilẹ̀kùn ò ní tì mọ́ ẹ lọ́wọ́

Gbogbo ọmọ ṣiṣẹ́ ṣiṣẹ́ ẹ ẹ̀ ní padà d’atọrọjẹ

Bí wọ́n bá ń pin lógún lógún

Bí wọ́n ń pin lọ́gbọ̀n lọ́gbọ̀n

Ìlẹ̀kùn ò jí tì mọ yín

Ohun gbogbo tí ẹ bá ṣe

Á bójú Ọlọ́hun Ọba ńlé Àyìndé mi Wasiu

Gbogbo yín ẹ kú ọdún

Kore, ọmọ ti hennessy baby naira máa gbọ́ bí mo ṣe ń wí

L’ágàràú area, Hennessy Nasiru ló bí wọn

Fuad ọmọ Ọlọ́tọ̀ ló fẹ́ ẹ

Túnjí ọmọ Ọláwuyì mo ṣì ń bọ̀ lórí

Mò ń gbéjà bọ̀ lórí ẹ̀

O ṣé ọmọ Bákàrè ó ń gbọ́

Ọmọ Ọlọ́tọ̀ mi (ọmọ Ọlọ́tọ̀ mi)

Owó ọkọ Kore, o ò dẹ̀ ní dọlárẹ̀yìn (Ọmọ Ọlọ́tọ̀ ni)

Kúlúsọ Kúlúsọ Abiamọ fẹ̀yìn sọ

Ọmọ Bákàrè, Kúlúsọ Kúlúsọ (Abiamọ fẹ̀yìn sọ)

Korede, Kúlúsọ Kúlúsọ (Abiamọ fẹ̀yìn sọ)

Kore, Kúlúsọ Kúlúsọ ( Abiamọ fẹ̀yìn sọ)

Kúlúsọ Kúlúsọ ( Abiamọ fẹ̀yìn sọ)

Fuad ọmọ Ọlọ́tọ̀, Kúlúsọ Kúlúsọ (Abiamọ fẹ̀yìn sọ)

Nínú ọdún yìí, kó j’ówó l’Ọlọ́hun fún ẹ (Abiamọ fẹ̀yìn sọ)

Àyìndé mi kò tí ì tó (Abiamọ fẹ̀yìn sọ)

Bó o bá jayé títí ko má gbàgbé Dangote ( Abiamọ fẹ̀yìn sọ)

Kúlúsọ Kúlúsọ ( Abiamọ fẹ̀yìn sọ)

Ọkọ Kóredé (Ọkọ Kóredé)

Òṣì kan ò mà ní ẹ ta (Ọkọ Kóredé)

Ìyá kan ò mà ní ẹ ẹ́ jẹ o (ọkọ Kóredé)

Ẹ bá mi kí ọmọ Ọlọ́tọ̀ (ọkọ Kóredé)

Bó o bá jayé títí Ọlọ́tọ̀ má gbàgbé Àlàbí Akínṣìkù (ọkọ Kóredé)

Ẹ bá mi kí Fuad (ọkọ Kóredé)

Yí ó da fún ọ tí ọ́ pọ̀ (ọkọ Kóredé)

Kò dẹ̀ ní yẹ̀ sílẹ̀ (ọkọ Kóredé)

Ah Kò dẹ̀ ní yẹ̀ sílẹ̀ (ọkọ Kóredé)

Ẹ̀yin mọdé wọ̀nyí, ẹ̀ ń yí mi lórí

Ẹ ṣe kòní yẹn fún mi (Adé orí ọ̀kín)

Ayọ̀ ọmọ Bákàrè

Ẹ̀yin mọdé wọ̀nyí ẹ ṣe kí í yẹn fún mi (Bàbá olóyè ló ń bọ́)

This is 2025

Ọdún tá n wí ti (ọdún tá n wí ti dé)

Ire gbogbo inú ọdún yìí, kà má mọ́ wọn Elédùmarè

(Ọdún tá n wí ti dé)

Owó ná ń ní nínú ọdún yìí ní ti dáadáa, owó àlùbáríkà, owó àlàáfíà, kà mí mọ́ wọn

Mo bẹ̀ẹ́ Elédùmarè (ọdún tá n wí ti dé)

Ah Jí’ọ́n mọ̀

Wọ́n gbàá l’ádùúà, wọ́n sọ fún wa ní’fá

Wọ́n ní tá a bá ṣe é ní Pẹ̀lẹ́ Pẹ̀lẹ́

2024,òjó ṣú afẹ́fẹ́ ń fẹ́

Ìjì ń jà, ewé oko, igi oko, gbogbo ẹ̀ fì sọ́tùn-ún, ó ń fì s’ósì

Ìjí jà títí kò d’omi inú àgbọn nù

Wọ́n ní bá a bá fi ré kọjá ẹ̀, tá a wọ 2025

Ah, wọ́n ní ọdún tá a ń sọ (ọdún tá a wí ti dé)

Wọ́n ní ọdún tá a ń sọ (ọdún tá a wí ti dé)

Wasiu Àyìndé, mo f’Ọlọ́hun búra (ọdún tá a wí ti dé)

Ìwọ náà bó bá jẹ́ omi lásán lo bá ń tà

Gbà pé Ọlọ́hun ò sùn, ilẹ̀kùn ti ṣí

Owó tá a ń sọ (ọdún tá a wí ti dé)

Wasiu Àyìndé, mo f’Ọlọ́hun búra (ọdún tá a wí ti dé)

Bó bá jẹ́ motor lò ń tà, to ròbí ò ń ta motor

Èyí tó o máa tà nínú ọdún yìí, yí ó ju ọdún ẹ̀ṣín lọ

(ọdún tá a wí ti dé)

Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fowó ṣòwò àpamọ́wọ́ owó wa (ọdún tá a wí ti dé)

A à ní ṣòwò àṣẹdànù bó w’ọlá Ọlọ́hun (ọdún tá a wí ti dé)

Gbogbo ẹ̀yin kọ́lékọ́lé, tí ẹ̀ ń ra’lẹ̀ tí ẹ̀ ń kọ́lé Ayọ̀ ọmọ Bákàrè

Gbogbo yín tí ẹ̀ ń fowó kọ́lé, tí ẹ̀ ń rà á

Tí ẹ̀ ń kọ́lé, tí ẹ̀ ń rà á, tí ẹ̀ ń tà á

Gbogbo wa àpamọ́wọ́ owó wa o (ọdún tá n wí ti dé)

Ihun kí’hun tó o bá ń tà, tó o bá dé síbẹ̀ báyìí

Gbàrànmí Gbàrànmí, wọ́n máa gbàràn ẹ́ lọ́tùn-ún, wọ́n máa gbà ràn án ẹ́ lósì

Ọrọ̀ tá a wí 2025, gbogbo ire tá a ń sọ (ọdún tá a wí ti dé)

Àyìndé mo f’Ọlọ́hun búra (ọdún tá a wí ti dé)

Mo f’Ọlọ́hun búra (ọdún tá a wí ti dé)

2025, owó ńlá ńlá

Ibi ńlá ni wọ́n ń p’erin sí, ibi ńlá ni wọ́n ń p’ẹfọ̀n sí

Màlúù tó ní kì í, bí èyí tó ń bẹ ní Farm Adégoróyè, Ah

Ẹran ńlá nínú ilé wa (ọdún tá a wí ti dé)

Mò ń gbà á ládùúrà fún’ra mi gba tì ẹ náà

Ìwọ náà fi tì ẹ síbẹ̀, ohun gbogbo tí kò ń sọ (ọdún tá a wí ti dé)

Bó bá jẹ́ owó lo bá fẹ́ owó náà á pọ̀ (ọdún tá a wí ti dé)

Bó jẹ́ ojú ọmọ lo bá ń wò lọ́wọ́ Ọlọ́hun (ọdún tá a wí ti dé)

Ìwọ náà á rí tì ẹ gbà, bó bá wọlá Ọlọ́hun o (ọdún tá a wí ti dé)

Ẹlẹlẹ Maiko, ìbejì méjì ń bọ̀ wá (ọdún tá a wí ti dé)

Ìbejì méjì ń bọ̀ wá (ọdún tá a wí ti dé)

Jẹ́jẹ́ Mero ìbejì méjì ń bọ̀ wá (ọdún tá a wí ti dé)

Ó máa ta helicopter o ma ta plane Ẹlẹlẹ bó w’ọlá Ọlọ́hun (ọdún tá a wí ti dé)

Ọdún owó là ń sọ o (ọdún tá a wí ti dé)

Ó pọ̀ Ọdún owó là ń sọ o (ọdún tá a wí ti dé)

Ah

Ẹlẹlẹ Maiko mi (Maiko mi)

Ẹlẹlẹ Maiko mi (Maiko mi)

Owó ọkọ Mosúnmọ́lá ìbejì ń bọ̀ (Ẹlẹlẹ Maiko mi)

Ba r’ẹ́ni tó bá torí mi Àyìndé lọ já gbẹ́rẹ́

Sese mi Modina, ó ku oríire fún tp’ọjọ́ ìbí ẹ

Ìyàwó Mercury aya Mujaidu Sese, aya Mercury mo kí ẹ

Modinatu kú oríire

Sese ṣe Ọmọlúwàbí o

(Oh yes)

(L’àgbà àti ọmọdé ṣe ń fẹ ẹni ayé bá ń fẹ́)

(Kò alárùn kan lára)

Modinatu Sese ṣe Ọmọlúwàbí o

(Oh yes)

(T’àgbà àti ọmọdé ṣe ń fẹ ẹni ayé bá ń fẹ́)

(Kò alárùn kan lára)

Mo kí ẹ kí ẹ Modina mi Sese

Aya Mujaidu káre l’ẹ̀pẹ́ ilé, fún tp’ọjọ́ ìbí ẹ Modinatu o

Ẹ̀mí ẹ á ṣe púpọ̀ ọdún láyé lówó lọ́mọ àti àlàáfíà o

Kay! Kay Nation bàbá ọkọ Sese mi sweetie Modina

O kú ọdún o, mo kí ẹ Kay Nation

Mercury mi (Mercury mi)

Mujaidu, Ẹ̀pẹ́ nílé alárọ̀ (Mercury mi)

Mujaidu, Ẹ̀pẹ́ nílé alárọ̀ (Mercury mi)

Modinatu Sese ṣe Ọmọlúwàbí o

(Oh yes)

(T’àgbà àti ọmọdé ṣe ń fẹ ẹni ayé bá ń fẹ́)

(Kò alárùn kan lára)

O kú oríire (o kú oríire)

Sese fún ọjọ́ ìbí ẹ (O kú oríire)

Ọkọ ẹ ní ń kí ẹ o (ó kú oríire)

Bàbá ọkọ ẹ Kay Nation, òun náà ní n kí ẹ (ó kú oríire)

Èmi náà ń kí ẹ o (ó kú oríire)

Mercury, èmi náà ń kí ẹ (ó kú oríire)

Ọkọ Sese Modinatu (ó kú oríire)

Ọkọ Sese Modinatu (ó kú oríire)

Media ẹ̀mí ẹ á ṣe púpọ̀ ẹ̀ (o kú oríire)

Mo kí ẹ fún tp’ọjọ́ ìbí ẹ (o kú oríire)

Modina ọlọ́rẹ (Modina ọlọ́rẹ)

Modina ọlọ́rẹ (Modina ọlọ́rẹ)

Ìyàwó Mercury (Modina ọlọ́rẹ)

Ìyàwó Mercury (Modina ọlọ́rẹ)

Ìyàwó Mujaidu (Modina ọlọ́rẹ)

Modinatu o (Modinatu)

Sese mo kí ẹ (Modinatu)

Ìyàwó Mujaidu (Modinatu)

Mujaidu Ẹ̀pẹ́ alárọ̀ o (Modinatu)

Yí ó da fún ọ tí ọ́ pọ̀ (Modinatu)

Ẹ̀mí á ṣe púpọ̀ ẹ̀, wàá ṣe ọ̀pọ̀ ọdún Sese