wa La Dé (Live)-文本歌词

wa La Dé (Live)-文本歌词

K1 De Ultimate
发行日期:

Adé orí ọ̀kín o o Adé orí ọ̀kín o o Gbogbo wa pátápátá ni mo kí A kú ọdún thank you Bí wọ́n ń pé àwa la dé o (Àwa la dé) Bí wọ́n ń pé àwa la dé o (Àwa la dé) Àyìndé ti dé (k’álára ṣọ́’ra) Arábámbí ti dé (k’álára ṣọ́ra) Ajá tó ṣeré lọ́sànán lò sọ́dọ̀ Ògìdán (Ó ní láti sán bàǹtẹ́ rẹ̀ ó) Ẹ̀ jẹ́ kí wọ́n má bọ̀ wá Ajá tó ṣeré lọ́sànán lò sọ́dọ̀ Ògìdán (Ó ní láti sán bàǹtẹ́ rẹ̀ ó) Ayé T’ẹ́nìkan ń yọ́ jẹ (T’ẹ́nìkan ń yọ́ jẹ) (Ayé T’ẹ́nìkan ń yọ́ jẹ) (Làwọn kan ń jẹ ṣúà bí ẹni jẹ iṣu) Ayé T’ẹ́nìkan ń yọ́ jẹ (T’ẹ́nìkan ń yọ́ jẹ) (Ayé T’ẹ́nìkan ń yọ́ jẹ) (Làwọn kan ń jẹ ṣúà bí ẹni jẹ iṣu) Àmọ̀kẹ́ bí èèyàn bá ṣe gbogbo nǹkan Ọmọ́gbọ́láhàn ó yẹ kó dúpẹ́ Ọpẹ́ ni mo dú lọ́wọ́ Ọlọ́hun Ọba First of January mọ́jú second, àríyá ọdún là ń ṣe Arábámbí Lọ́jọ́ tí a yà sílẹ̀ tí a fi ń dúpẹ́ oore Ọlọ́hun ni Wasiu Àyìndé Ẹ̀dá ò dàbí Ọlọ́hun, bí ẹ̀dá bá dàbí Ọlọhun ni ọmọ ẹ̀dá ò ní rọ̀jò o Àyìndé adé wọn ò ní jẹ́ a rówó ná Ẹ jẹ́ n kà á síwájú Wọ́n ó le, wọn ò le bá o (Wọ́n ó le wọn ò le bá) Wọ́n ó le, wọ́n ó le, wọ́n ó le, wọ́n ó le, wọ́n ó le, wọn ò le bá o (Wọ́n ó le wọn ò le bá) O lọ mọ́ wọn lọ́wọ́ baba Faruku (Wọ́n ó le wọn ò le bá) O lọ mọ́ wọn lọ́wọ́ o ti ṣẹ́ corner (Wọ́n ó le wọn ò le bá) Ẹṣin tó síwájú ni wọ́n ń pè ní Master (Wọ́n ó le wọn ò le bá) Ẹni Ọlọ́hun Ọba fẹ́ òun l’Ọlọ́hun mi yàn (Wọ́n ó le wọn ò le bá) Mo lọ mọ́ wọn lọ́wọ́ mo ti ṣẹ́ corner o (Wọ́n ó le wọn ò le bá) Mo dúpẹ́ Ọlọ́hun Arábámbí Mo tún wá ń bẹ̀ ẹ́ Ọlọ́hun A ti bọ́ sí ọdún tuntun báyìí Jẹ́ á mọ ọdún náà sí dáadáa Ká ma bá wọn kú’kú kú’kú Ká má ṣe bá wọn dùbúlẹ̀ àìsàn Ire gbogbo kó ṣojú wa Wasiu Àyìndé Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́hun tí à ń dúró Àyìndé mi tí à ń wò lójú Ká má ṣe ká’wọ́ lérí sunkún 2025, ọdún ayọ̀ ni ó jẹ́ kó jẹ fún gbogbo wa Ìsọ̀wọ́ ká tà ká rà ká nílárí Gbogbo ọmọkùnrin ọmọbìnrin tí wọ́n ń t’ẹpá m’ọ́ṣẹ́ K’ẹ rí ìdùnnú Ọlọ́run nínú ọdún tuntun Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń f’owó ṣòwò arábámbí Alágbèédá má ṣe gbé wa lọ́sàn-án lóru Iṣẹ́ ìṣe wa kó bọ́ sí dáadáa fún wa arábámbí Ẹ̀yin oníṣẹ ìjọba kẹ̀dẹ̀ rèé Ọkọ Ọba àdá Ọba ìyẹn ò ní ṣá wa lésẹ̀ Amina Àwa tí a wá ń sáré wí pé kó le bọ́si Wí pé kó le dára á dára lójoojúmọ́ Lórí ọmọ wa lórí aya wa Ọdún eléyìí ọdún owó ló máa jẹ́ o Ire tí wọ́n ti ń sọ tẹ́lẹ̀ kó máa wọlé wá Jẹ́ ó tẹ̀ kí lọ́wọ́ Ọlọ́hun Ọba Ẹ̀bẹ̀ ni mo fi ṣe mi ò fi ṣe akọ Ọmọ́gbọ́láhàn arábámbí Ìwọ lo ni Risiku lọ́dọ̀ Ọlọ́hun Fi risiku ko fi sẹ́nu corner mi K1 De Ultimate Àyìndé Wọ́n ó le, wọn ò le bá o (Wọ́n ó le wọn ò le bá) O lọ mọ́ wọn lọ́wọ́ baba Faruku (Wọ́n ó le wọn ò le bá) O lọ mọ́ wọn lọ́wọ́ baba Fatimo (Wọ́n ó le wọn ò le bá) Ẹni ru kánún ṣubú pẹ̀rẹ́ ló bá bú sẹ́kún (Kíni k’ẹ́lẹ́yin tútù kó máa ṣe ajá tó bá ń bá ẹkùn dùnà ẹ̀sín nirúu wọn) Dìgbòlẹ̀gún dìgbòlẹ̀gún mo rí yẹn dájú (Labalábá ytó dìgbòlẹ̀gún ayé ẹ má da lẹ́kun, láìpẹ́ yó di alákìísà nínú aṣọ) Ẹ mọ̀ pé Àkèékèé kò ṣe é gbé s’ábíyá (Ẹni tó dán irú ẹ̀ wo níjọ́sí ará mi, níṣe ló j’ọ́lọ́hun nípè ẹ̀yin ará wa) A wí wọ́n ní wọn ò gbọ́ o, wọ́n ń j’ápá mọ́nú (Tí wọ́n bá pàdée wanígbàlẹ̀ ẹ tẹrí ba fún wa, àwa lagbólóhùn bí ọ̀jẹ̀ t’a bá délé orin) Àkùkọ tó rí kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ tó ń ré kọjá (Tó sì wá ń gbọ̀n’yẹ́ pẹ̀pẹ̀ kí ló máa rí’ṣe?) (Egele á gbé ìṣe ẹ̀ wò ẹ̀yin aráa wa) Lecture là ń ṣe( kìí ṣe ìjà o) Lecture là ń ṣe (Mú tákàdá kẹ mú gègé ẹ wá gbórí tó mọ́gbọ́n dání tèwe àgbà o mọ́gbọ́láhàn gbọ́ pọ́n ńlá dé) (Àwa làgbà o Wese boy ti d’Ọba orin) Lecture là ń ṣe( kìí ṣe ìjà o) Lecture là ń ṣe (Mú tákàdá kẹ mú gègé ẹ wá gbórí tó mọ́gbọ́n dání tèwe àgbà o mọ́gbọ́láhàn gbọ́ pọ́n ńlá dé) (Àwa làgbà o Wese boy ti d’Ọba orin) Àfòpiná o tó Lege o ti ṣe àdúrà Bentley Ṣé ọpẹ́ bentley lo mú wá yìí, Lege Miami Torí mo ti ṣe àdúrà Bentley fún Lẹ́gẹ́ Lege Miami, ọdún tó kọjá lọ Lege Ó ní Àyìndé ṣ’àdúrà ilé ńlá wọlé Ó ti wá lọ́dún yìí o Kí n tó dé’bí, ó lóun tún fẹ́ gbàdúrà ọdún Mo ní wà á ra Bentley Wasiu Àyìndé Ehn ehn, ìdá mẹ́wàá tèmi lo mú wá Lege mo dúpẹ́ Ọlọ́hun Ọba Lege owó ọpẹ́ ni (owó ọpẹ́ ni) Lege Miami, gbogbo ọmọkùnrin tó ń wá’ya Ọmọbìnrin tó ń wọ́’kọ Ẹ pé Lege, lege Miami mi o Lege owó ọpẹ́ ni (owó ọpẹ́ ni) Lege Miami owó ọpẹ́ ni o (owó ọpẹ́ ni) CEO Singles hookup CEO Singles hookup Ọ̀rẹ́ Ṣèyí ọmọ Tinúubú mi ST ST ìyẹn Ọ̀rẹ́ Lege Miami Lege Lege Lege wà á ṣe wọ́pọ̀ ọdún láyé Lege máa sọ fún wọn Alápá yẹbẹyẹbẹ níbo lẹ̀ ń lọ (Ajùdí yàbàyàbà níbo lẹ mí rè) Alápá yẹbẹyẹbẹ níbo lẹ̀ ń lọ (Ajùdí yàbàyàbà níbo lẹ mí rè) (Kò s’ẹ́ni tó le nà ẹ́ lọ́rẹ́ lójú tani Ṣèyí mi ST o) (Kò s’ẹ́ni tó le nà ẹ́ lọ́rẹ́ lójú tani Aṣíwájú of Lagos) Gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ tí wọ̀n ń sọ má wo’bẹ̀ bo bá ń gbọ́ Lege, kiní kan ò mà ní lè ṣe (Gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ tí wọ̀n ń sọ má wo’bẹ̀ bo bá ń gbọ́) Ìwọ lọba Hookup, kiní kan ò le ṣe (Gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ tí wọ̀n ń sọ má wo’bẹ̀ bo bá ń gbọ́) Ọlá bàbá Adémidé bàbá Mercy Lege kiní kan ò le ṣe (Gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ tí wọ̀n ń sọ má wo’bẹ̀ bo bá ń gbọ́) kiní kan ò le ṣe (Gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ tí wọ̀n ń sọ má wo’bẹ̀ bo bá ń gbọ́) Ọba Hookup kiní kan ò le ṣe (Gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ tí wọ̀n ń sọ má wo’bẹ̀ bo bá ń gbọ́) Mò ń wá’ya ó pàdé mò ń wọ́kọ lọ́dọ̀ Lege Miami Kiní kan ò le ṣe (Gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ tí wọ̀n ń sọ má wo’bẹ̀ bo bá ń gbọ́) Olúayé Fújì (Ọ̀gá wa o)