Hunter (Live)-文本歌词

Hunter (Live)-文本歌词

K1 De Ultimate
发行日期:

Hunter mi (Hunter mi) Òun l’onínàwó èní ẹ jọ̀ọ́ ẹ jẹ́ k’óun nìkan ó jó Hunter ijó ọpẹ́ lo jó mi ò fẹ́ Naira Dollar tó ò fún mi nílùú America O ò fún mi nílùú Canada Mi ò dẹ̀ worry ẹ torí pé o wà lójú iṣẹ́ Mo rí pé o rán owó níṣẹ́ owó náà á padà Lágbára Ọlọ́run Ọba ojú ò kí ń t’ère Ojú òní tì ẹ́ Hunter A ti dé Nàìjíríà ńṣe ni o lówó wá Hunter Naija ná ń pe’bí ìṣe ni o lówó wá Dollar ni o ná fún èmi Èyí tí mo ní o ná ní Washington àti ti Houston àti Maryland àti t’Atlanta Georgia àti New York pẹ̀lú Chicago Indiana àti the Troy o ní láti ná gbogbo ẹ̀ àti Los Angeles TÓ ń bọ̀ tó ṣì wà níwájú T’ẹ́ ẹ bá fẹ́ kí n wá Hunter lówó tó pọ̀ fún èmi Kòsí èyí tó o fún mi tí kìí ṣ’owó Ìbáà jẹ́ Canadian dollar Lówó púpọ̀ fún èmi Jaccuzi bí ènìyàn bá fún mi lówó Canada ilé ni mò ń ko lọ Màá kó ìyẹn dé Toronto Walahi mo f’Ọlọ́hun búra Ọlọ́hun á bù sápò Hunter Èyí tó o kọ́ yẹn, lágbára Ọlọ́hun Ọba Kiní kan ni mo fẹ́ o ṣe Ọlọ́hun á ṣọ́ gbogbo wa ju ọdún tó ń bọ̀ À ń dájọ́ a ò ní dájọ́ lé ikú lọ́wọ́ Ojú u wa á pé, ẹsẹ̀ ẹ wa á pèlé Nínú ọlá ńlá nínú àlàáfíà Hunter Lọ́dún tó ń bọ̀ Ẹ ní láti modify ibí yìí kó big ju báyìí lọ K1 De Ultimate irú stage ọdún tó kọjá ibẹ̀ yẹn lẹ fi sí Ó da bẹ́ẹ̀ Èyí tí à ń ṣe tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ẹ̀yìn lọ́tùn-ún ni stage wa Ó da bẹ́ẹ̀, bí ẹ ṣe ń yí ọwọ́ ẹ̀ padà Kòsí ohun tó burú níbẹ̀ Ṣùgbọ́n tó bá possible láti ibí débi tí Canada wà níiwájú Ẹ jẹ́ kí stage àárín kó dá sọ́nà méjì (Adé orí ọ̀kín) Ẹ wá ṣe platform, ẹ gbé ìyẹn sókè níbẹ̀yẹn Irú èyí tá a ṣe tẹ́lẹ̀ tàwọn èèyàn tí wọ́n wà lókè Hunter èèyàn tó fẹ́ ṣiṣẹ́ promotion kìí ṣe ojọ́ kan Kìí ṣe show kan ni wọ́n fi ń r’ówó náà padà Ṣùgbọ́n ihun téèyàn ti tò sílẹ̀ tó ń ṣe lọ́dọọdún Ìgbà tí wọ́n bá máa yọ́ you spend less You make triple profit á máa lọ sókè Expansion ó ti ń wá àìmọye èèyàn tí ò wá’bí Tí ò wá’bí tẹ́lẹ̀ tẹ́lẹ̀ tí wọ́n fẹ́ máa wá Modúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ Hunter Support tó o fún Music entertainment lójoojúmọ́ láti ibí dé America arábámbí Last America tí mo lọ ìwọ àti Mike ọmọ Fáṣakin bó ṣe dúró tìí Ojú ì í t’ère ojú òní tì ẹ́ modúpẹ́ dúpẹ́ Wizzy máa wolẹ̀ (máa wolẹ̀ máa rọra) Wizzy wizzy máa wolẹ̀ Èní yẹ ẹ́ o Hunter Ṣé o rí’hun tí kò ń sọ? Ọmọ mi máa wolẹ̀ Wizzy wizzy mo kí ẹ Wizzy wizzy mo kí ẹ Wizzy, máa wolẹ̀ máa rọra Wizzy yí ó da fún ọ tí ó pọ̀ o Òun náà wá jó’jó ọdún Wizzy mi (wizzy mi) Ọmọ Balógun Dòdóńdáwà níjẹ̀bú òde Wizzy wizzy ọmọ mi (wizzy mi) Ọmọ Alhaji Muniru níjẹ̀bú Òde Wizzy máa wolẹ̀ máa wolẹ̀ máa rọra) Ẹ jẹ́ ó kalẹ̀, kó máa jayé orí ẹ̀ Femo! Femo! Wizzy mi, (wizzy mi) Wizzy wizzy ọmọ mi (Wizkid mi) Ọmọ Moráyọ̀ wizzy wizzy ọmọ mi (Wizkid mi) #INSTRUMENTAL Wizzy wizzy ọmọ mi (wizkid mi) Ìjẹ̀bú lọlá wà (Wizkid mi) Polanco Ìjẹ̀bú lọlá wà (Wizkid mi) Polanco dà? Ìjẹ̀bú lọlá wà (Wizkid mi) Ayọ̀ níjẹ̀bú Òde o (Wizkid mi) Ikú òní pa ọmọ náà lọ́wọ́ ẹ (wizkid mi) Wizzy wizzy ọmọ mi (Wizkid mi) Wizzy wizzy ọmọ mi (Wizkid mi) Arábámbí Mo ṣì ń sọ̀rọ̀ modification Mò ń sọ̀rọ̀ Hunter ṣé o rójú ayé Alfa sọ̀rọ̀ òjò kù ó ní Ọlọ́hun Ọba Ó ní ó gbẹ̀rí òun jẹ́ Irú situation báyìí yí ó ṣẹlẹ̀ arábámbí Lọ́dún tó ń bọ̀ àwọn èèyàn pàtàkì Wizzy ló wá lọ́dún yìí Lọ́dún tó ń bọ̀ ó súre jù David máa wá Ìfẹ́ l’Ọlọ́hun Ọba ló ní a ní síra wa Ẹ̀yin náà ò bàjẹ́ K1 De Ultimate Arábámbí Ẹ̀yin òní camera okay now Ẹ ẹ̀ lè báwọn wí Wọ́n rí International star ẹ ní kí wọ́n má gbe Wọ́n ní láti gbe, ẹ jọ̀ọ́ ẹ ṣiṣẹ́ ọwọ́ (ẹ ṣiṣẹ́ ọwọ́ọ yín) Ṣùgbọ́n ìròyìn tó da ni kẹ́ ẹ gbé Ihun tó da ni kẹ́ ẹ sọ nípa wa Ọdún tuntun ṣá lawà yìí Ọ̀rọ̀ àkówábá ká má ri o (ẹ ṣiṣẹ́ yín) Irú àwọn ọmọ olóríire báyìí t’Ọ́lọ́hun Ọba fi kẹ́ wa ní Nàìjíríà Àwọn tó ju àwa lọ King Adéníyì mi Sunny Adé Owonkwo international Fẹlá Aníkúlápó Owonkwo International Fẹ́mi Aníkúlápó Owonkwo International Sikiru Àyìndé Barrister Owonkwo International K1 De Ultimate Arábámbí Olúayé Fújì Owonkwo International Àkànbí Sir Shina Peters Ayé wá d’ayé àwọn mọdé wọ̀nyí gbogbo wọn ni wọ́n ń ṣe dáadáa Lámidé Baddo, Burna boy, Wizzy, Ọlámidé, David ọmọ Adélékè Lọ́wọ́ lọ́wọ́ Tems pẹ̀lú Ayra Star Gbogbo wọn ń jayé orí Africa lọ́wọ́ lọ́wọ́ yìí Africa ló ni Entertainment Àyìndé adé mi ọ̀rọ̀ ni Àwọn ọmọ tẹ̀yin náà á dàgbà wọ́n á ṣoríire Ẹ̀ ẹ́ bímọ bíi Wizzy á mówó wálé Ẹ̀ ẹ́ bímọ bíi Davido á mówó wálé Ẹ̀ ẹ́ bímọ bíi Ayra star K1 De Ultimate Ọlọ́hun á máa gbàdúrà gbogbo wa Polanco owó ọkọ Mosúnmọ́lá Èèyàn ọmọ Bello mo gbà fún ẹ tó Polanco, o ò dẹ̀ ní dọlárẹ̀yìn o Ifá tí mo dá láìpẹ́ wàá bẹ̀rẹ̀ sí ní ta Helicopter Àyìndé ní Nàìjíríà níbí Òyìnbó America wàá ko wálé Wàá f’owó gbàá, ìwọ á tàá Wàá rí dọ́bùrù dọ́bùrù Wàá ta Aeroplane bó bá wọlá Ọlọ́hun àmín o Wàá fìdí kalẹ̀ sí Ògùn State a ti ní airport l’ógùn Airport ó ń bẹ Àyìndé Bẹ bá dé ìlíṣan àti ìpẹru a ní airport International Ogun state Gateway International Airport ó ń bẹ níbẹ̀ Arábámbí Mo f’Ọlọ́hun búra ọ̀rọ̀ ni Ẹ kọ́’lẹ̀ Ẹlẹlẹ Mesiko ó ti dájú O ò dẹ̀ ní dọlárẹ̀yìn Arábámbí Ọmọ Imam àgbà … Arábámbí Ńṣe là ń fọlá rayì náà ni Ọmọ Bello Bellodos A kì í láhun níyì ló dífá fún náwó náwó Náwó náwó ń fowó rayì náà ni Ihun wù ẹ ko fowó ẹ rà tèmi dámi lójú Bí ń bá lówó lọ́wọ́ ó arábámbí N ó fowó rayì náà ni