TRIBUTE TO MY MOTHER-文本歌词

TRIBUTE TO MY MOTHER-文本歌词

K1 De Ultimate
发行日期:

Ẹ má bìínú pípẹ́ tí mo pẹ́ lẹ́yìn Mo lọ ṣe t’ọmọ lórí òbí ẹni ìyá mi Alimo Sadia Sadia relé, thank you Alimo Sadia ó relé Kò kọ́kọ́ yé mi àfi ìgbà tí àwọn ayé ń kími pé mo kú oríire arábámbí Irú oríire kínni? Kí ìyá ẹni ó kú Ọmọ tí ò ní rí màmá ẹ̀ mọ́ o Wọ́n wá ń sọ fún mi wí pé o ti ṣẹ́gun oṣó O ṣẹ́gun àjẹ́ torí kínni? Ọmọ tó bá gbẹ̀yìn òbí ẹ̀ òun l’Ọlọ́hun Ọba ń fẹ́ Àìmọye èèyàn ni wọ́n ń retí irú èyí Ìyá tó bí wọn ó ti lọ ò ní kékeré Àwọn òbí wọn f’ayé lẹ̀ ìgbà tí wọ́n ń bẹ lọ́mọdé Èmi dúpẹ́ Ọlọ́hun Alimotu Sadia ọmọ Akérédolú Ọmọ Ọba nìlúpéjú Èkìtì aya Ọba níjẹ̀bú òde Ìyá mi Alimo Sadiatu o Ó kọjá Ọgọ́rùn-ún kó tó relé lọ sùn ọmọ Anífowóse Ọlọ́hun bàbá mo dúpẹ́ (Arabic Recitation) Ṣùgbọ́n irú ọjọ́ èní bí ǹ bá wábí Wasiu arábámbí Ará a mi ò ní balẹ̀ ọmọ Anífowóṣe o ọmọ òkú ọ̀run Mufuti, Mufti ó tóbi lọ́wọ́ mi Wasiu Àyìndé Yàtọ̀ sí pé nínú ẹ̀sìn very very important Ń ṣe ni Suleiman Iṣan ọrùn Adégoróyè tipẹ́tipẹ́ A sì ti jọ ń ṣeré bọ̀ lọ́mọdé Sheu Farouq àdúrà ẹ ti gbà lórí wa Àmọ̀pé Sadia ti lọ Automatic o ti gbẹ́wù yẹn wọ̀ Kò ní wọ̀ ẹ́ lọ́rùn Àmín Wàá ṣe ìyá fún mi pẹ́ Ramotallahi mi Àmọ̀pé adé o Àmọ̀pé adé wàá ṣe ìyá fún mi pẹ́ pẹ́ pẹ́ lowú ń ṣ’arọ́ Mo kí ẹ kí ẹ Àmọ̀pé o O kú oríire Àmọ̀pé adé Alhaja Ramota KC KC Ẹ gbówó náà jáde (Adé orí ọ̀kín) Ìyá mi kú, owó la máa ná A máa kó dollar jáde (owó la máa ná) Olorì Mariam aya onílé òrìṣà máa wolẹ̀ máa ràba aya t’Ọ̀nirìṣà Owó la máa ná Seida, kẹ ya kó dollar jáde (Owó la máa ná) Dàmọ́lá, Anifata Monsuratu owó la máa ná Miwa sọ fún ọkọ ẹ ẹ lọ kó dollar jáde (owó la máa ná) Bosede ẹ kó dollar jáde (owó la máa ná) Orí ò ṣe wá lọmọ olókùú ò sí nílé Wasiu Àyìndé mo dúpẹ́ fún Ọlọ́run (Adé orí ọ̀kín) Wọ́n ń bi ẹ́ Muhammadu Kazeem ọmọ Owólabí Wọ́n ní ṣe o léèyàn, o ló o lẹ́ni lẹ́yìn ẹ o Wọ́n ní tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ìrìn-àjò bíi wákàtí méjì Gbé phone àwọn èèyàn láàrin Ìṣẹ́jú kan sí ìkẹta Ko sì fún wọn lásìkò kí wọ́n gbórí wọlé Gbogbo yín ẹ kú àdúrótì mi Díẹ̀ ṣá ni mo pè Ọmọtógbọ́láhàn igba ló jẹ́ mi Ẹ̀yin èèyàn ló ń bẹ lẹ́yìn òrò arábámbí Àlàmú adé ọkọ Ọmọ́táyọ̀ mi Àlàmú o ṣeun o Àdúrà ẹ á máa gbà lójoojúmọ́ Àlàmú tẹ rí yẹn èèyàn ni Kazeem Owólabí mi èèyàn ni Moshood Ajide tẹ rí yẹn èèyàn ni Gbogbo yín ẹ kú àdúrótì mo dúpẹ́ dúpẹ́ dúpẹ́ Mo tú pẹ̀pẹ́ ọpẹ́ dá Muhammadu Kazeeme Sheikh Isiak ọmọ Agbariigidana ẹ kú àdúrótì mo dúpẹ́ dúpẹ́ Mo dúpẹ́ dúpẹ́ Imam NANWAT Àyìndé mi Wasiu mo dúpẹ́ dúpẹ́ Imam Ẹ̀pẹ́, Àkànní Akumari ọmọ Adéṣọpẹ́ Ètí inú Gbogbo èèyàn everybody wọ́n wá ń wọlé Àkànbí olódó idẹ Presidenti mo dúpẹ́ dúpẹ́ Ọmọ Habibatu Àkànbí ọmọ ìyálọ́jà bàbá ìyálọ́jà Ó ní Habiba ìyálọ́jà àgbà àti Alimotu Sadia ó ní wọ́n ti jọ ríra wọn báyìí Wọ́n dẹ̀ ń ṣe ìpàdé, ó ní kí gbogbo àdúrà máa lọ beeee Àkànbí mo dúpẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ bàmi Ó dẹ̀ ṣe ní àdúrà fún mi ó ní ojú mi ò ní ríbi Ó ní ìyá kan ò ní jẹ ẹ́ ọmọ òkú ọ̀run A ò dẹ̀ kí ń lẹ́ni lẹ́yìn kíyá ó tún jẹni President mo dúpẹ́ dúpẹ́ His Excellency Babájídé ọmọ Sanwóolú Deputy Governor Hamzat Ọbáfẹ́mi Governor Dàpọ̀ Abíọ́dún Governor Ṣèyí Mákindé mo ki yín ẹ kú àdúrótì mo dúpẹ́ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ kálukù ni wọ́n gbórí wọlé Àdìsá bí èèyàn bá lẹ́yìn arábámbí Ẹsékẹsẹ̀ ni Bíọ́lá ló volunteer ó lẹ́yin ẹ máa lọ sìnkú Òun ma lọ sékòó òun á lọ stand in ọmọ á jẹ́ ẹ Wàá pe èèyàn márùn-ún igba ló máa jẹ́ ẹ Àmín o O kú àdúrótì wọ́n pínṣẹ́ fúnra wọn ni Bọ́ládé ìyẹn re Central mosque ó lọ di mọsalasi mú Ó di baba mesinku òun pẹ̀lú ofulu gbogbo wọn ni wọ́n ìdílé mú Abíọlá àní èèyàn mẹ́wàá lo máa pè igba ló máa jẹ́ gbogbo wọn Alao Sulemona ó gbórí wọlé Bí a ṣe dé mọ́ṣáláṣí Ajibola Pasuma ó gbórí wọ̀lé Gbogbo wọn ń pè mí lọ́tùn-ún lósì ẹ kú àdúrótì mo dúpẹ́ dúpẹ́ Ìyẹn lẹni àkọ́kọ́ pè Àdùnní Risikiyatu Afọláshadé Ọlámilékan olóòtú ọlọ́lá Madasa gbogbo Akilẹ̀ Ìjẹ̀bú Bó ṣe ṣẹlẹ̀ gbàrà egúngúngbohùn ó ń gbọ́ Ó dẹ̀ dé ìlú Ìjẹ̀bú Òde Gbogbo yín ẹ kú àdúrótì mo dúpẹ́ dúpẹ́ Adégbóyèga Alátiṣe Mutiu ọmọ Ààrẹ òun ló wá ṣe aṣojú aṣojú President arábámbí On behalf of Ọ̀yọ́ State Owóṣeéní Fatai ó gbórí wọlé Fìjàbí onílẹ̀ obì Akin ó move gbogbo èrò láti Ìbàdàn l’Ólúyọ̀lé ilé kún Abdulwasiu ọmọ Jẹ́nrádé ìlú bàbá Isah Ẹlẹlẹ l’Ólúyọ̀lé ilé Gbogbo yín mo dúpẹ́ dúpẹ́ fún èró pọ̀ A ò lè pe gbogbo èèyàn tán Bí a ṣe ń kúrò nítẹ́ Àyìndé Musiliu Ayédáadé Òun náà gbórí wọlé sílùú Ìjẹ̀bú Òde Kábíèsí Awùjalẹ̀ Ọba Adéwájú Ọlọ́jà nílùú Ẹ̀pẹ́ ilé àti Aláyélúwà tuntun Kábíèsí ìmọ̀pẹ̀ Ọba mẹ́ta ní ọ̀pẹ̀ mi Kábíèsí láti makun omi, Kábíèsí Àkárìgbò Kábíèsí Alárá èrò pọ̀ lọ rẹpẹtẹ Bí a ṣe ń kọ Inalilahi Fẹ́mi Gbàjàbíàmílà a jọ ń ke ni K1 De Ultimate ta fi gbé ṣẹ Kábíèsí Makun omi gbogbo ẹ̀yin Ọba ládé ládé Orímolúsì Ìjẹ̀bú Igbó Èbúmàwá àgọ́ Kábíèsí Ọ̀gọ̀gọ̀ Àti Òrúgbò Kábíèsí Òrúgbò ẹ kú àdúrótì mo dúpẹ́ dúpẹ́ Baba wa Àkànní mi Rasaki Eleganza Ọkọya Àti Afọlashadé Ìṣẹ́jú Ìṣẹ́jú Àyìndé mi ni wọ́n ń pè Wọ́n sì ń ṣ’àdúrà fún mi K1 De Ultimate Wọ́n ní o kú oríire Àyìndé o