APPRECIATION-文本歌词

APPRECIATION-文本歌词

K1 De Ultimate
发行日期:

Ó da ká lẹ́ni lẹ́yìn Àdìsá Béèyàn bá lẹ́ni lẹ́yìn bí Ọba ló kúkú rí Ara àwọn ọmọ Olóòkú tí wọ́n gbé gbogbo ẹ̀ lórí Àrẹ̀mú Adébáyọ̀ ọmọ Ọláṣojú Ọlámilékan Gaji mi bàbá mesiku Jí ‘ọ́n mọ̀ mi (Jí ‘ọ́n mọ̀ mi) Òun àti Bísọ́lá mi jí’ọ́n mọ̀ (jí’ọ́n mọ̀ mi) Mr Monsuru mr Mosh ọmọ ọ̀dọ̀ àgbà rere Gbogbo yín ẹ kú àdúrótì (Adé orí ọ̀kín) Èró pọ̀ níjẹ̀bú òde (Adé orí ọ̀kín) Aya mi Àjíkẹ́ mi Ella (Adé orí ọ̀kín) Àti Àdufẹ́ Fathia Ọpẹ́yẹmí Gbogbo àwọn ọmọ àti ọmọ ọmọ gbogbo wọn ni wọ́n péjú Àńjọláolúwa òun ni wọ́n ní ó sọ̀rọ̀ Òun ni kékeré inú wọn (Àbíkẹ́ adé) Ìyá mi Àbíkẹ́, sùn un re lọ́run Àbíkẹ́ adé ọmọ Akérédolú Àbíkẹ́ adé ọmọ Ọba aya Ọba Sùn un re bo bá ti d’ọ́run Àbíkẹ́ Ìyá mi Àbíkẹ́ o Mother Sherifatu mother Wasiu Àyìndé Mother Múfútáù mi Mother Ramotalahi Oríyọmí Ìfánúìyá Ìyá mi Àbíkẹ́ o Sùn-ùn re to bá ti d’ọ́run Alhaji Wasiu Àyìndé (Ìyá mi Àbíkẹ́ o) Abiamọ gidi ni ẹ́ Àbíkẹ́ mo mọ̀ ọ́n lóore fún bíbí tó o bí mi Títọ́ tó o tọ́ mi Wíwò tó o wò mí Mo wá ń dúpẹ́ Ọlọ́hun Ọba Bo ṣe bá mi sọ̀rọ̀ Àbíkẹ́, Abiamọ dáadáa Sùn-un re bo bá ti d’ọ́run Àbíkẹ́ Ìyá mi Àbíkẹ́ o Abiamọ pàtàkì sinmi nínú Ọlọ́hun má ro’rẹ Àbíkẹ́ (Ìyá mi Àbíkẹ́) Sherifa ilé fọwọ́ ẹ má mikàn ṣé o gbọ́ (Ìyá mi Àbíkẹ́ o) Ìwọ lolúwájú o ò dẹ̀ ní dọlárẹ̀yìn Sherifatu Àdùnní o (Ọmọ Ìyá mi Àbíkẹ́ o) Ọmọ yín lèmi jẹ́ o Alhaji Wasiu Àyìndé (Ìyá mi Àbíkẹ́ o) Àyìndé Arábámbí K1 De Ultimate mo dúpẹ́ dúpẹ́ Abíọ́lá Béèyàn ò bá dúpẹ́ lọ́wọ́ olóore bí abaramóorejẹ ni O ò dẹ̀ ní dọlárẹ̀yìn Abíọ́lá ọmọ Débímpé nílùú Ìjẹ̀bú Òde Béèyàn bá lọ́mọ lẹ́yìn ọmọ gidi tó dúró tó péjú owó Tó o bá délé Ishola Musiliu kó o bá mi ki Ọmọ Haruna Bello bá mi ki bo bá délé Ní mo ní kó bámi kí Misitura kó bá mi ki Sule ọmọ Yusuf alága ìjọba surulere Òun náà ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló gbọ́ ló délé Ó dẹ̀ fẹ̀yìn mọ́ mi Alhaji Wasiu Arábámbí àti Àkànní Akumari ọmọ Adéṣọpé Àti Délékẹ kúyẹ̀ Abíọ́lá mi Dickson, Kọ́ládé Ọ̀nánúgà Honourable Adémọrìn kúyẹ̀ mi Gbogbo àwọn Ọ̀túnba ní Akilẹ̀ Ìjẹ̀bú wọ́n ń ṣe ìpàdé lọ́wọ́ Gnogno wọn ló fi ilé ẹgbẹ́ sílẹ̀ Àyìndé mọ́gbọ́láhàn Wọ́n jẹ́ mi ní gbèje gbẹ̀jọ Gbogbo Ọ̀túnba Akilẹ̀ Ìjẹ̀bú Àbọlọrẹ ọmọ lótùpà bétí ẹ bá ń já nílùú Ìjẹ̀bú Òde Mé le gbàgbé yín Ofuluọlà mi o kú àdúrótì Ofulu o ṣọmọ f’Alimotu Sadia tó fi jáde láyé Ọlọ́hun á bámi dúpẹ́ fun Àmín o Ofulu o ò dẹ̀ ní dọlárẹ̀yìn mo dúpẹ́ dúpẹ́ dúpẹ́ O ò j’ójú ó tìmí K1 De Ultimate gbogbo yín ni mo dúpẹ́ fún Kábíèsí Awùjalẹ̀ Iba ẹni Kábíèsí wọ́n ní lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ẹ lọ ṣí mọ́ṣáláṣí ńlá Central Mosque Ibẹ̀ lẹ tí máa kírun si lára Alimotu Sadia ìyá olórí ọmọ Ọba Baami Ọ̀gbágbá agbọ́tẹ̀wọlẹ̀ Aníkinláyà mo kí ẹ baàmi Abímbọ́lá ọmọ Òkè ńlá nílùú Ìjẹ̀bú Òde Òun ni kakaǹfò gbogbo yín ni mo dúpẹ́ fún Ọlámilékan ọmọ Ọ̀ṣífẹ̀sọ̀ Ọ̀lọ́wá nílùú Ìjẹ̀bú Òde Jìnmí ọmọ Lawali mi olootu Ìfọ̀rẹ́ Mé le gbàgbé yín Àdùnní Risikatu Afọlashadé aya Adéṣọyè Risika O mà kú àdúrótì ọmọ ni ẹ́ Àdùnní ó ń pè mí ní gbèje gbẹ̀jọ aya Akilẹ̀ Démọ́lá Morufa Ìkòròdú ọ̀gá ọmọ t’oríwu mo dúpẹ́ dúpẹ́ o kú àdúrótì Ọláitán Pẹ̀lú Bukky (pẹ̀lú Bukky mi) Bùkọ́lá ọmọ Araga (pẹ̀lú Bukky mi) Àdùnní mi Kudira Yétúndé ọ̀rẹ́ mi (Kudiratu mi) Kudira ọ̀rẹ́ mi (Kudiratu mi) Ọpẹ́ Ọlọ́tọ̀ (ọpẹ́ Ọlọ́tọ̀ mi) Ó dúró wam! Ọpẹ́ Ọlọ́tọ̀ (ọpẹ́ Ọlọ́tọ̀ mi) Àìpẹ́ náà l’olórí ọ̀dọ́ Okado Deji wọlé wẹ́rẹ́ wẹ́rẹ́ Gbogbo àwọn ẹgbẹ́ gbogbo wọ̀n ni wọ́n dé Inúùmídùn pátápátá láti orí olórí ẹgbẹ́ Déńdè Ọmọ t’Egúngúngbohùn mo kí ẹ kí ẹ Ah! Ọpẹ́ Ọlọ́tọ̀ (Ọpẹ́ Ọlọ́tọ̀ mi) Àti Olúwafẹ́mi Ṣótirẹ̀ Ọ̀rẹ́ mi Àjàní Bàsíà mi o níṣe ni wọ́n ń pè ní gbèje gbẹ̀jọ Àjàní mi Bọ́lájí Ọkọ Bukky mi Àjàní adé Anderson láti Toronto mi Gbogbo yín ẹ kú àdúrótì o Ìṣẹ́jú Ìṣẹ́jú ni wọ́n ń pè Prince George Àlàmú Bashiru Fákóredé ó dúró wam KC! ọmọ Owólabí ó dúró wam Moshood ọmọ Àjídé ó dúró wam! Àkànbí ọmọ ólódó idẹ Aṣíwájú ẹ kú àdúrótì mo dúpẹ́ dúpẹ́ dúpẹ́ dúpẹ́ Àkànbí mé le gbàgbé ẹ o Àkànbí ń bẹ nílùú Dubai nínú Plane lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n pè wọlé Wọ́n ń kí ọmọ olókùú Wọ́n ní mo mú oríire, o kú ó lédè màmá ẹ Governor Babájídé ọmọ Sanwóolú ó ní lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ mo máa dé lọ́la pẹ̀lú deputy Obafemi hamzat mi Dàpọ̀ Abíọ́dún títí ni n ó máa ṣe Ìdúpẹ́ Ah Ṣèyí ọmọ Makin (Ṣèyí ọmọ Mákindé) Àìmọye Senator lóríṣiríṣi (adé orí ọ̀kín) Àìmọye Honourable lóríṣiríṣi (adé orí ọ̀kín) Ah! Àrẹ̀mú mi Báyọ̀ ọmọ Ọláṣojú Ọmọ mi Àrẹ̀mú mi Báyọ̀ ọmọ Ọláṣojú Àti Ayọ̀ọlá Fatai bàbá Ọláṣojú Pẹ̀lú Sulemona Sule Moyọ̀ ọmọ ògúnlẹ̀wẹ́ (Moyọ̀ ọmọ Ògúnlẹ̀wẹ́) Moyọ̀ ọmọ Ogunlẹ̀ (Moyọ̀ ọmọ Ògúnlẹ̀wẹ́) Àánú tí ń jẹ́ Rasheeda alága ìrù ó pè wọlé Àti Ọbasá Muda (Muda mi) Gbogbo yín ni mo dúpẹ́ fún ẹ kú àdúrótì (Adé orí ọ̀kín) Aṣíwájú inú ẹ á dùn (Àkànbí adé) Ọmọ ólódó idẹ Àkànbí inú ẹ á dùn (Àkànbí adé) Fasasi inú ẹ á dùn (Àkànbí adé) Yínká ọmọ Ajénifújà láti Àbújá ó pè wọlé K1 De Ultimate Adé orí ọ̀kín ah! Kábíèsí Àkárìgbò bàbá mi mo dúpẹ́ dúpẹ́ ẹ kú àdúrótì Aláyélúwà Àkárìgbò ní Rẹ́mọ Baami bí èèyàn bá ní ẹ lẹ́yìn ohun gbogbo ló ni Hamdah washukurah mo dúpẹ́ dúpẹ́ Gbogbo ilé Ọba l’Ákilẹ̀ Ìjẹ̀bú nílùú Ìjẹ̀bú Òde Ilé Ọba mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ẹ kú àdúrótì mo dúpẹ́ dúpẹ́ Fẹ́mi grandma yin tí lọ Alimotu Sadia Etí gan gbórí wọlé ìgbà tí wọ́n gbọ́ pé mo ti wá sí Èkó Ni wọ́n padà sílé o kú àdúrótì mo dúpẹ́ dúpẹ́ Ètí Davido ìwọ náà á dàgbà Etí ọmọ dábírà níjẹ̀bú òde Ọmọ Dábírà nílùú Ìjẹ̀bú Òde Fẹ́mi Marshal kó o bá mi jíṣẹ́ fún Basira Barrister Lawyer mi àti àwọn ẹ̀gbọ́n ẹ̀ Idayatu Bọ́lájí Àṣàkẹ́ àti Oríyọmí mi Amina Ìdẹ̀ra nimotallahi Afọlashadé àti òun àti ọkọ ẹ̀ Àyìndé mi Wasiu Sulemona olówó Yọ̀mádé mi Sule lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ó dé láti Ìbàdàn torí Granny ẹ̀ Àńjọláolúwa Àbíkẹ́ òun àti àwọn àbúrò ẹ Sawatu Arafa pẹ̀lú Melissa mi melikoko ọmọ mi Aya mi Àjíkẹ́ o Aya mi Àjíkẹ́ o Ẹlẹ́bà Yellow mi Emmanuella ló dílé mú (Aya mi Àjíkẹ́ o) Ẹlẹ́bà Yellow mi Àbíkẹ́ baby ló dilé mú (Aya mi Àjíkẹ́ o) Àwọn ọlọ́fadà gbórí wọlé láti Abẹ́òkúta Alhaji Wasiu Àyìndé (Aya mi Àjíkẹ́ o) Àti àdufẹ́ o (Fathia) Ọpẹ́yẹmí o (Àdufẹ́ mi o) Ọpẹ́yẹmí o (Àdufẹ́ mi o) Ọmọ Shehu èkó (Àdufẹ́ mi o) Ẹ kú àdúrótì mi (Àyìndé mi o) Ẹ mà kú àdúrótì mi (Àyìndé mi o) Ati ọmọ mi Àyọ̀ká o Gbogbo wọn ló gbórí wọlé Bíọ́lá oríishílè gbogbo wọn ló gbórí wọlé Limelite, Goldmyne gbogbo wọn ló gbórí wọlé Dior baby gbogbo wọn ló gbórí wọlé KC K1 gbogbo wọn ló gbórí wọlé Àti Dammy baby gbogbo wọn ló gbórí wọlé Èró pọ̀ rẹpẹtẹ, èró pọ̀ rẹpẹtẹ Gbogbo ẹgbẹ́ lẹ́yìn tí ẹ bá dé láti cotonou ọ̀sẹ̀ kan ẹ máa jẹ, ẹ máa mu Ẹ máa ná, ẹ máa ná million million Mò fẹ́ mo’ye tẹ́ ẹ fẹ́ ná láàrin oṣù kan K1 De Ultimate arábámbí Àyìndé o (K1 De Ultimate) Alimo Sadia mo fọlọ́hun ṣọ́ ẹ Bó o bá ti d’ọ́run sùn-un re Abiamọ ni ẹ́, o ṣe’hun Abiamọ ń ṣe Alimotu Sadia o Sùn-un re lọ́run mother Sherifa Mother Àyìndé Wasiu mi ọmọ Anífowóse Mother Múfútáù Babatunde Mother Ramotalahi Oríyọmí Àbíkẹ́ adé mi ọ̀run ẹ ẹ re Sùn-un re bo bá ti d’ọ́run ọmọba Ìlúpéjú Èkìtì Sùn-un re bo bá ti d’ọ́run màmá mi